Ìwé Saamu 54

Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ: dá mi láre nípa agbára rẹ. Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí. Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa, àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn. Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ. Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ. Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ, èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa, nítorí tí ó dára. Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Abonneer op onze nieuwsbrief

Blijf op de hoogte van nieuwe profielen, evenementen en platformupdates.