Ìwé Saamu 33

Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo; ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin. Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i. Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo. Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́. Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀. Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo. Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin. Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í. Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni. Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀. Olúwa wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn. Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn. A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀. Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀. Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn. Ọkàn wa dúró de Olúwa; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa. Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀, nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́. Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Abonneer op onze nieuwsbrief

Blijf op de hoogte van nieuwe profielen, evenementen en platformupdates.