Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ, àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè.Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọléàwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.