Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ; èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà; wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú; ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run; Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá, ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.Olúwa jẹ ọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni; kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀; àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí; jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa; jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.