Ìwé Saamu 122

Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.” Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ, ìwọ Jerusalẹmu. Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan. Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà Olúwa, ẹ̀rí fún Israẹli, láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa. Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀, àti ìre nínú ààfin rẹ̀. Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi èmi yóò wí nísinsin yìí pé, kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀. Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa, èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Iscriviti alla nostra newsletter

Resta aggiornato su nuovi profili, eventi e novità della piattaforma.