Ẹ máa yin Olúwa. Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo: àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀: òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé, mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.