Ìwé Saamu 137

Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni. Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò, tí ó wà láàrín rẹ̀. Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá; wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!” Àwa ó ti ṣe kọ orin Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀. Bí èmi kò bá rántí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo. Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu, lára àwọn ọmọ Edomu, àwọn ẹni tí ń wí pé, “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!” Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun; ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ bí ìwọ ti rò sí wa. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Assinar nossa newsletter

Mantenha-se a par dos novos perfis, eventos e novidades da plataforma.