Ìwé Saamu 123

Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run. Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa. Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀. Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Subskrybuj nasz newsletter

Bądź na bieżąco z nowymi profilami, wydarzeniami i nowościami platformy.