Ìwé Saamu 11

Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé, “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ. Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀; wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìji sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?” Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò. Olúwa ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá ni ọkàn rẹ̀ kórìíra. Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó; àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn. Nítorí, olódodo ní Olúwa, o fẹ́ràn òdodo; ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Tilaa uutiskirjeemme

Pysy ajan tasalla uusista profiileista, tapahtumista ja alustan uutisista.