Ìwé Saamu 129

“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá,” jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí; “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá; síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi. Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn. Olódodo ni Olúwa: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.” Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà. Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè, èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀: bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé, ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Unseren Newsletter abonnieren

Bleiben Sie über neue Profile, Veranstaltungen und Plattform-Updates informiert.