Ìwé Òwe 21

Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa; a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi. Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀, ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn. Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ. Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni! Ètè àwọn olóye jásí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá. Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú. Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ, nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́. Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́. Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n, nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀. Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́. Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò: àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle. Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́: ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye, yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú. Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin. Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n; ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá. Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára, ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu. Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀. Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé; nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe. Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́: ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró. Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni: mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi? Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró. Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le: ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa. A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun: ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Unseren Newsletter abonnieren

Bleiben Sie über neue Profile, Veranstaltungen und Plattform-Updates informiert.