Ìwé Saamu 113

Ẹ máa yin Olúwa. Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ yin orúkọ Olúwa. Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn. Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run. Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa, tí ó gbé ní ibi gíga. Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé! Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá. Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yin Olúwa.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

الاشتراك في نشرتنا الإخبارية

ابقَ على اطلاع بالملفات الجديدة والفعاليات وتحديثات المنصة.