Ìwé Saamu 48

Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀. Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè Sioni, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá. Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára. Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀, wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ. Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n, a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ. Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí. Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ìlú Ọlọ́run wa, Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela. Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run, àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run, ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé, ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo. Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn nítorí ìdájọ́ rẹ. Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀. Kíyèsi odi rẹ̀, kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀. Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé, Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Bíbélì Yorùbá

copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc — CC-BY-SA-4.0 — CC-BY-SA-4.0

Misoratra ao amin'ny gazety anay

Mahafantara hatrany ny mombamomba vaovao, ny hetsika ary ny fanavaozana ny sehatra.